Hymn 516 – OLUGBALA mi, ife Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUGBALA mi, ife Re" (C&S Hymn #516, Yoruba). OLUGBALA mi, ifẹ Rẹ, Ha tobi bẹ si mi? Wo, mo f'ile mi, ọkan mi, At'aya…
OLUGBALA mi, ifẹ Rẹ, Ha tobi bẹ si mi? Wo, mo f'ile mi, ọkan mi, At'aya mi fun Ọ. Mo fẹ Ọ nitori 'toye, Ti mo ri ninu Rẹ Mo fẹ Ọ nitori iya, T'O f'ara da fun mi. Bi Iwọ ti jẹ Ọlọrun, T'a f'ogo de l'ade, Iwọ ko kọ awọ eniyan, T'o kun fun iyọnu. 'Wọ jẹ k'a bi Ọ l'eniyan, Sugbọn 'Wọ ko l'ẹsẹ; K'awa le ri b'Iwọ ti ri, K'a le se b'O ti se. K'a dabi Rẹ ninu ifẹ, L'ẹwa iwa mimọ, B'a ti ń woju Rẹ, k'a ma lọ, Lat'ogo de ogo. AMIN
Hymn 516 – OLUGBALA mi, ife Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia