Hymn 492 – JESU, 'Wo n'ibi sadi mi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU, 'Wo n'ibi sadi mi" (C&S Hymn #492, Yoruba). JESU, 'Wọ n'ibi sadi mi, 'Wọ ni mo gbẹkẹle; Ọrọ Rẹ n'iranlọwọ mi;…

Hymn 492 – JESU, 'Wo n'ibi sadi mi | C&S Yoruba Hymnary
JESU, 'Wọ n'ibi sadi mi, 'Wọ ni mo gbẹkẹle; Ọrọ Rẹ n'iranlọwọ mi; Emi alailera; N ko ni ẹjọ kan lati ro, Ko s'ohun ti n ó wi, Eyi to, pe Jesu mi ku, Jesu mi ku fun mi. Igba iji 'danwo ba n ja, T'ọta n dojukọ mi, Itẹ anu n'isadi mi, Nibẹ n'ireti mi, Ọkan mi yoo sa tọ Ọ wa, 'Gba 'banujẹ ba de; Ayọ ọkan mi l'eyi pe, Jesu mi ku fun mi. Larin iyọnu t'o wuwo; T'eniyan ko le gba; Larin ibanujẹ ọkan, Ati 'rora ara ; Kil'o le funni n'isinmi, Ati suru b'eyi? T'o n s'eleri l'ọkan mi pe, Jesu mi ku fun mi. 'Gba ohun Rẹ ba si pasẹ, K'ara yi dibajẹ, Ti ẹmi mi, b'isan omi, Ba si san kọja lọ, B'ohun mi ko tilẹ jalẹ, Nigba naa, Oluwa, Fun mi n'ipa ki n le wi pé, Jesu mi ku fun mi. AMIN

Hymn 492 – JESU, 'Wo n'ibi sadi mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia