Hymn 048 – O TI TO Jesu f' gbara | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "O TI TO Jesu f' gbara" (C&S Hymn #048, Yoruba). 1. O TI TỌ Jesu f' agbara 'wẹnumọ, A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan; Iwọ ha…

Hymn 048 – O TI TO Jesu f' gbara | C&S Yoruba Hymnary
1. O TI TỌ Jesu f' agbara 'wẹnumọ, A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan; Iwọ ha gbẹkẹle ore-ọfẹ Rẹ, A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan. A wẹ ọ, ninu ẹjẹ, Ninu ẹjẹ Ọdaguntan, fun ọkan Asọ rẹ ha funfun o si mọ laulau: A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan. 2. O mba Olugbala rin lojojumọ; A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan; O sinmi le ẹni ti a kan mọ'gi, A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan, 3. Asọ rẹ funfun lati pade Oluwa, O mọ lau ninu ẹjẹ Ọdaguntan; Ọkan rẹ mura fun 'le didan loke, K'a wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan 4. Bọ ẹwu eri ẹsẹ si apa kan, Ko si wẹ ninu ẹjẹ Ọdaguntan; Isun kan n san fun gbogbo ọkan aimọ, Jọ lọ wẹ ninu ẹjẹ Ọdaguntan. AMIN

Hymn 048 – O TI TO Jesu f' gbara | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia