Hymn 444 – AIGBAGBO, bila! temi l'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AIGBAGBO, bila! temi l'Oluwa" (C&S Hymn #444, Yoruba). AIGBAGBỌ, bila! temi l'Oluwa, Oun o si dide fun igbala mi; Ki n…
AIGBAGBỌ, bila! temi l'Oluwa, Oun o si dide fun igbala mi; Ki n sa ma gbadura, Oun o se ranwọ; 'Gba Krist' wa lọdọ mi, ifoya ko si. B'ọna mi ba su, Oun l'o sa n tọ mi, Ki n sa gbọran sa, Oun o si pese, Bi iranlọwọ ẹda gbogbo saki, Ọrọ t'ẹnu Rẹ sọ y'o bori, dandan Ifẹ t'o n fi han ko jẹ ki n ro pe, Y'o fi mi silẹ ninu wahala; Iranwọ ti mo si n ri lojojumọ, O n ki mi laya pe, emi o la ja. Emi o se kun tori ipọnju, Tabi irora? O ti sọ tẹlẹ! Mo m'ọrọ Rẹ p'awọn ajogun 'gbala, Wọn ko le s'aikọja larin wahala. Ẹda ko le sọ kikoro ago, T'Olugbala mu, k'elẹsẹ le ye; Ayé Rẹ tilẹ buru ju temi lọ, Jesu ha le jiya, k'emi si ma sa! Njẹ b'ohun gbogbo ti n sisẹ ire, Adun n'ikoro, Ounjẹ ni ogun; B'oni tilẹ koro, sa ko ni pẹ mọ, 'Gbana orin 'sẹgun yoo ti dun to! AMIN
Hymn 444 – AIGBAGBO, bila! temi l'Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia