Hymn 435 – Emi ko wa oro aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Emi ko wa oro aye" (C&S Hymn #435, Yoruba). Emi ko wa ọrọ ayé, O pese f'aini mi, Sugbọn n ó nọga siwaju, F'oju to mu…

Hymn 435 – Emi ko wa oro aye | C&S Yoruba Hymnary
Emi ko wa ọrọ ayé, O pese f'aini mi, Sugbọn n ó nọga siwaju, F'oju to mu hanhan, Ki n gbẹkẹle Ọ Oluwa, F'ore-ọfẹ ojojumọ. Gba naa l'ọkan mi o kọrin, Labe agbelebu; Nitori 'sinmi dun l'ẹsẹ Krist' Gba mo fi 'gbagbọ re 'le (2) N ki y'o nani ohun ayé, T'o n rọgba yi mi ka, Sugbọn n ó f'ayọ sa 'pa mi, Iyoku d'ọwọ Rẹ; O daju p'ere didun wa, F'awọn to sinmi l'Oluwa, Gba naa l'ọkan mi o kọrin, Labe agbelebu; Nitori 'sinmi dun l'ẹsẹ Krist' Gba mo fi 'gbagbọ re 'le (2) N' ki y'o sa f'agbelebu mi, Ohun t'o wu k'o jẹ, Sugbọn ki n sa le wa fun Ọ, Ki n sa se ifẹ Rẹ, Ki n' se 'fẹ Rẹ lojojumọ, Gba mba fi 'gbagbọ Sunmọle. Gba naa l'ọkan mi o kọrin, Labe agbelebu; Nitori 'sinmi dun l'ẹsẹ Krist' Gba mo fi 'gbagbọ re 'le (2) Gba mo ba pari isẹ mi, Ti mo kọja odo, Oluwa jọ jẹ k'ọkan mi, Le ba Ọ gbe titi, Ki n kọ'hun ti mo mọ nihin, Bi'fẹ Rẹ ti pọ si mi to. Gbana l'ọkan mi o kọrin, Labẹ agbelebu; Nitori 'sinmi dun l'ẹsẹ Krist' Gba mo fi 'gbagbọ re 'le (2) AMIN Gbana l'ọkan mi o kọrin, Labẹ agbelebu; Nitori 'sinmi dun l'ẹsẹ Krist' Gba mo fi 'gbagbọ re 'le (2)

Hymn 435 – Emi ko wa oro aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia