Hymn 422 – TERUTERU t'iyanu ni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "TERUTERU t'iyanu ni" (C&S Hymn #422, Yoruba). TẸRUTẸRU t'iyanu ni, Ọlọrun mi da mi, Gbogbo awọn eya ara mi, Isẹ iyanu…
TẸRUTẸRU t'iyanu ni, Ọlọrun mi da mi, Gbogbo awọn eya ara mi, Isẹ iyanu ni. Nigba t'a da mi n'ikoko, O ti mọ ara mi; Ẹya ara mi l'O si mọ, Sa t'ọkan wọn ko si. Ọlọrun, iro inu Rẹ, Se 'yebiye fun mi; Iye wọn pọju iyanrin, Ti ko sẹni le ka. B'o ti mọ ẹda mi bayi, Wadi ọkan temi; Mu mi mọ ọna Rẹ lailai. Si ma to ẹsẹ mi. AMIN
Hymn 422 – TERUTERU t'iyanu ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia