Hymn 412 – LO, l'ooro kutukutu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "LO, l'ooro kutukutu" (C&S Hymn #412, Yoruba). LỌ, l'oorọ kutukutu, Lọ, ni ọsan gangan, Lọ, ni igba asalẹ, Lọ, ni…

Hymn 412 – LO, l'ooro kutukutu | C&S Yoruba Hymnary
LỌ, l'oorọ kutukutu, Lọ, ni ọsan gangan, Lọ, ni igba asalẹ, Lọ, ni ọganjọ oru, Lọ, t'iwọ t'inu rere, Gbagbe ohun ayé, Si kunlẹ n'iyẹwu rẹ, Gbadura nikọkọ. Ranti awọn t'o fẹ Ọ, At' awọn t'iwọ fẹ; Awọn t'o korira rẹ; Si gbadura fun wọn; Lẹyin na, tọrọ 'bukun, Run 'wọ tikalarẹ; Ninu adura rẹ, ma Pe orukọ Jesu. B'ayé ati gbadura, Ni kọkọ ko si si, T'ọkan rẹ fẹ gbadua, 'Gbana, adura jẹjẹ, Lat'inu ọkan rẹ, Y'o de ọdọ Ọlọrun. Ọlọrun Alanu. Ko si ayọ kan l'ayé, T'o si ju eyi lọ; Ni t'agbara t'a fun wa, Lati ma gbadura; 'Gba t'inu rẹ ko ba dun, Jẹ k'ọkan rẹ wolẹ; Ninu ayọ rẹ gbogbo, Ranti or'-ọfẹ rẹ. AMIN

Hymn 412 – LO, l'ooro kutukutu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia