Hymn 397 – BAWO ni awon ewa wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BAWO ni awon ewa wa" (C&S Hymn #397, Yoruba). BAWO ni awọn ẹwa wa, Y'o ti ma sọra wọn? Bikose nipa 'kiyesi, Gẹgẹ bi…
BAWO ni awọn ẹwa wa, Y'o ti ma sọra wọn? Bikose nipa 'kiyesi, Gẹgẹ bi ọrọ Rẹ. 'Gba ọrọ na wọ'nu ọkan, A tan imọlẹ ka; Ọrọ na kọ ope l'ọgbọn, At'imọ Ọlọrun. Ọrun ni, imọlẹ wa ni, Amọna wa l'ọsan; Fitila ti n f'ọna han wa, Ninu ewu oru. Ọrọ Rẹ, otọ ni titi, Mimọ ni gbogbo rẹ; Amọna wa l'ọjọ ewe, Ọpa l'ọjọ ogbo. AMIN
Hymn 397 – BAWO ni awon ewa wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia