Hymn 390 – E FI ogo fun Baba | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E FI ogo fun Baba" (C&S Hymn #390, Yoruba). Ẹ FI ogo fun Baba, Nipa Ẹni ti a wa; O n gbọ adura ewe, O n f'eti si orin…
Ẹ FI ogo fun Baba, Nipa Ẹni ti a wa; O n gbọ adura ewe, O n f'eti si orin wọn. Ẹ fi ogo fun Ọmọ, Kristi, 'Wọ ni Ọba wa; Ẹ wa, ẹ kọrin s'oke, S'Ọdaguntan ẹlẹsẹ. Ogo fun Ẹmi Mimọ, Bi ọjọ Pentikosti; Ru aya awọn ewe, F'orin mimọ s'ete wọn. Ogo ni l'oke ọrun, Fun Ẹni Mẹtalọkan; Nitori ihin rere, Ati ifẹ Ọlọrun. AMIN
Hymn 390 – E FI ogo fun Baba | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia