Hymn 038 – DIDUN n'ise na, Oba mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "DIDUN n'ise na, Oba mi" (C&S Hymn #038, Yoruba). 1. DIDUN n'isẹ na, Ọba mi, Lati ma yin Orukọ Rẹ; Lati se'fẹ Rẹ…
1. DIDUN n'isẹ na, Ọba mi, Lati ma yin Orukọ Rẹ; Lati se'fẹ Rẹ l'owurọ, Lati sọ ọrọ Rẹ l'alẹ. 2. Didun l'ọjọ 'sinmi mimọ, Lala ko si fun mi loni, Ọkan mi ma kọrin iyin, Bi harpu Dafidi didun. 3. Ọkan mi o yọ n'Oluwa, Y'o yin isẹ at'ọrọ Rẹ; Isẹ oore Rẹ ti pọ to! Ijinlẹ si ni imọ Rẹ. 4. Emi o yan ipo'ọla, Gb'ore-ọfẹ ba wẹ mi nu; Ti ayọ pupọ si ba mi, Ayọ mimọ lat'oke wa. 5. 'Gbana, n o ri, n o gbọ, n o mọ, Ohun gbogbo ti mo ti n fẹ, Gbogbo ipa mi y'o dalu, Lati se'fẹ Rẹ titi lai. AMIN
Hymn 038 – DIDUN n'ise na, Oba mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia