Hymn 335 – A KAN Krist' Irekoja mo agbelebu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A KAN Krist' Irekoja mo agbelebu" (C&S Hymn #335, Yoruba). A KAN Krist' Irekọja mọ agbelebu, O kigbe oro wi pé,…
A KAN Krist' Irekọja mọ agbelebu, O kigbe oro wi pé, ―Igbala pari. O jọwọ ẹmi rẹ lọwọ fun irapada Ẹda, O sun ninu iboji, o di asẹgun. O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni. Jesu Oluwa Iye, o wa tọ'ku wo, Iku ati ipo oku ko tun n'ipa mọ: Ẹ f'ogo fun Ọlọrun, fun 'sẹgun lor'iku O sọ oro iku d'asan f'awa ẹlẹsẹ. O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni. Ọba Olupilẹsẹ Iye ti jinde, O di akọbi ninu awọn ti o sun, 'Wọ Alfa at'Omega, Ipilẹsẹ at'opin, 'Wọ ni isika iku at'ipo oku. O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni. Jesu nip' ajinde Rẹ sọ ẹmi wa ji, Ji wa n'nu iku ẹsẹ s'iye ododo, K'ajinde ara le jẹ tiwa, K'ifẹ oun Alafia, Ma gbilẹ ninu ayé gẹgẹ bi t'ọrun. O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni. Jesu Oluwa Iye se 'lẹkun iku, F'ọm'Ẹgbẹ Séráfù ati Kérúbù, Iye ni tiwa titi l' ayé yi ati l'ọrun; A o si jọba pẹlu Rẹ lai ati lailai. O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni. AMIN O jinde, O jinde, Jesu, Ọba Iye, O jinde, O jinde, O jinde loni.
Hymn 335 – A KAN Krist' Irekoja mo agbelebu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia