Hymn 311 – JESU Oluwa awa de | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU Oluwa awa de" (C&S Hymn #311, Yoruba). JESU Oluwa awa de, Loni Ọjọ Ajinde wa, Lati gb'ọkan s'oke, Si Orukọ rẹ…

Hymn 311 – JESU Oluwa awa de | C&S Yoruba Hymnary
JESU Oluwa awa de, Loni Ọjọ Ajinde wa, Lati gb'ọkan s'oke, Si Orukọ rẹ Mimọ ni. Ba wa pe Ọlọrun Baba, Ba wa pe Ọlọrun Ọmọ Ba wa pe Ọlọrun Ẹmi Wa sọ gbogbo wa di mimọ. Lọjọ oni, awa dupẹ, Tẹru tẹru l'awa jọsin Gba wa lọwọ ayé osi yi, Ma jẹ k'a s'ẹsin layé yi. Hosanna s'Ọba Olore, A dupẹ fun Ajinde yi, F'Ẹnikan naa to jinde, A sọpẹ fun Mẹtalọkan. Ogo ni fun Baba l'oke, Ogo ni fun Ọmọ pẹlu, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Ogo ni f'Olodumare. AMIN

Hymn 311 – JESU Oluwa awa de | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia