Hymn 309 – OKUN l'ale, tutu n'ile | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OKUN l'ale, tutu n'ile" (C&S Hymn #309, Yoruba). APA I p OKUN l'ale, tutu n'ile, Nibi Kristi wolẹ, Ogun Rẹ bi iro ẹjẹ,…

Hymn 309 – OKUN l'ale, tutu n'ile | C&S Yoruba Hymnary
APA I p OKUN l'ale, tutu n'ile, Nibi Kristi wolẹ, Ogun Rẹ bi iro ẹjẹ, Ninu 'waya ija. Baba gba'go kikoro yii, B'o ba se ifẹ Rẹ; Bi bẹkọ, Emi o si mu, Ifẹ Rẹ ni k'a se. Ẹlẹsẹ lọ wo l'agbala, Ẹjẹ mimọ wọnni; p O r'ẹru wuwo ni fun ọ, O rẹ 'ra 'lẹ fun ọ. Kọ lati gbe agbelebu, Se ifẹ ti Baba; Nigba idanwo sunmọle, Ji sore, gbadura. AMIN APA II KI Jesu ha nikan jiya, K'arayé lọ lofo? Iya mbẹ f'olukuluku; Iya si mbẹ fun mi. Em'o ru agbelebu mi, Tit' iku y'o gba mi; 'Gbana, n ó lọ 'le lọ d'ade, 'Tor'ade mbẹ fun mi. Nile ita kristali na, Lẹba ẹsẹ Jesu, N ó f'ade wura mi lelẹ; N ó yin orukọ Rẹ. A! agbelebu! A! ade! A! ọjọ ajinde! Ẹyin Angel ẹ sọkalẹ, Wa gbe ọkan mi lọ. AMIN

Hymn 309 – OKUN l'ale, tutu n'ile | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia