Hymn 307 – 'WỌ t' bẹbẹ f'ọta Rẹ | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'WỌ t' bẹbẹ f'ọta Rẹ" (C&S Hymn #307, Yoruba). ỌRỌ MEJE KRISTI LORI AGBELEBU ―Baba dariji wọn, nitori ti wọn ko mọ…

Hymn 307 – 'WỌ t' bẹbẹ f'ọta Rẹ | C&S Yoruba Hymnary
ỌRỌ MEJE KRISTI LORI AGBELEBU ―Baba dariji wọn, nitori ti wọn ko mọ ohun ti wọn n se.‖ - Luk. 23: 34. 'WỌ t' bẹbẹ f'ọta Rẹ, L'or' igi agbelebu: Wi pé,―fiji wọn Baba: Jesu, saanu fun wa. Jesu, jọ bẹbẹ fun wa, Fun ẹsẹ wa 'gba gbogbo; A ko mọ ohun t'a n se, Jesu, saanu fun wa. Jẹ k'awa ti n wa aanu, Dabi Rẹ l'ọkan n'iwa, 'Gba t'a ba se wa n'ibi: Jesu, saanu fun wa. ―Loni ni iwọ o wa pẹlu mi ni Paradise.‖ - Luk. 23: 43 Jesu, 'Wọ t'o gbọ aro, Ole t'o ku l'ẹgbẹ Rẹ, T'o si mu d'ọrun rere: Jesu, saanu fun wa. Ninu ẹbi ẹsẹ wa, Jẹ k'a tọrọ aanu Rẹ, K'a ma pe orukọ Rẹ: Jesu, saanu fun wa. Ranti awa ti n rahun, T'a n wo agbelebu Rẹ; F'ireti mimọ fun wa. Jesu, saanu fun wa. ―Obinrin, wo ọmọ rẹ, Wo iya rẹ.‖ - John 19: 26-27 'Wọ t'o fẹ l'afẹ dopin, Iya Rẹ t'o n kanu Rẹ, Ati ọrẹ Rẹ ọwọn: Jesu, saanu fun wa. Jẹ k'a pin n'nu iya Rẹ, K'a ma kọ iku fun Ọ, Jẹ k'a ri 'tọju Rẹ gba: Jesu, saanu fun wa. Ki gbogbo awa Tirẹ, Jẹ ọmọ ile kan naa; Tori Rẹ, k'a fẹ 'ra wa: Jesu, saanu fun wa. ―Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eese ti iwọ fi kọ mi silẹ.‖ - Matt. 27: 46 Jesu, 'Wọ ti ẹru mba, 'Gba t'o si ku 'Wọ nikan, Ti okunkun su bo Ọ: Jesu, saanu fun wa. 'Gba ti a ba n pe lasan, T'ireti wa si jina; N'nu okun na di wa mu: Jesu, saanu fun wa. B'o dabi Baba ko gbọ, B'o dabi 'mọlẹ ko si, Jẹ k'a f'igbagbọ ri Ọ. Jesu, saanu fun wa. ―Orungbẹ n gbẹ mi.‖ - John 19:30 Jesu, ninu oungbẹ Rẹ, Ni ori agbelebu, 'Wọ ti o fẹ wa sibẹ; Jesu, saanu fun wa. Ma koungbẹ fun wa sibẹ, Sisẹ mimọ l'ara wa; Tẹ ifẹ Rẹ na l'ọrun; Jesu, saanu fun wa. Jẹ k'a koungbẹ ifẹ Rẹ, Ma samọna wa titi, Sibi omi iye ni: Jesu, saanu fun wa. "O Pari" - 19:30 Jesu Olurapada, 'Wo t'o se'fẹ Baba Rẹ, T'o si jiya 'tori wa; Jesu, saanu fun wa. Gba wa l'ọjọ idamu, Se oluranlọwọ wa, Lati ma t'ọna mimọ: Jesu, saanu fun wa. F'imọlẹ Rẹ s'ọna wa, Ti y'o ma tan titi lai, Ti t'a o fi de ọdọ Rẹ: Jesu, saanu fun wa. ―Baba ni ọwọ Rẹ ni mo fi ẹmi mi le.‖ - Luk. 23: 46 Jesu, gbogbo isẹ Rẹ, Gbogbo idamu Rẹ pin: O jọw'ẹmi Rẹ lọwọ: Jesu, saanu fun wa. 'Gbat'iku ba de ba…

Hymn 307 – 'WỌ t' bẹbẹ f'ọta Rẹ | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia