Hymn 3 – BABA, a tun pade l'oko Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "BABA, a tun pade l'oko Jesu" (C&S Hymn #3, Yoruba). 1. BABA, a tún pade l'okọ Jesu, A si wa tẹriba lab'ẹsẹ Rẹ; A tun…

Hymn 3 – BABA, a tun pade l'oko Jesu | C&S Yoruba Hymnary
1. BABA, a tún pade l'okọ Jesu, A si wa tẹriba lab'ẹsẹ Rẹ; A tun fẹ gb'ohun wa soke si Ọ Lati wa aanu lati kọrin 'yin 2. f A yin Ọ fun itọju 'gba gbogbo, Ojojumọ l'a o ma royin sẹ Rẹ; Wiwa laye wa, aanu Rẹ ha kọ? Apa Rẹ lo fi ń gba ni mọra? 3. p O se! a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro lọdọ Rẹ pọju; mf Sugbọn kikankikan ni O si ń pe: Njẹ, a de, a pada wa'le Baba. 4. mp Nipa ookọ t'o bor'ohun gbogbo, Nipa ifẹ t'o ta'fẹ gbogbo yọ, Nipa ẹjẹ ti a ta fun ẹsẹ, Silẹkun aanu, si gbani s'ile. AMIN

Hymn 3 – BABA, a tun pade l'oko Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia