Hymn 029 – OLORUN wa orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN wa orun" (C&S Hymn #029, Yoruba). 1. ỌLỌRUN wa ọrun, T'o fi ọjọ mẹfa Da nkan gbogbo ti mbẹ layé, Sinmi nijọ…
1. ỌLỌRUN wa ọrun, T'o fi ọjọ mẹfa Da nkan gbogbo ti mbẹ layé, Sinmi nijọ keje. 2. O pasẹ k'a bọwọ Fun ọjọ sinmi; Ibinu Rẹ tobi pupọ S'awọn t'o rufin yi. 3. Awọn baba nla wa p Ti ku nin'okunkun; Wọn jẹ ogbo aborisa Wọn ko mọ ofin Rẹ. 4. Awa de, Oluwa, Gẹgẹ bi asẹ Rẹ, Lẹyin isẹ ọjọ mẹfa, Lati se ifẹ Rẹ. 5. Mimọ l'ọjọ oni; O yẹ ki a sinmi; K'a pẹjọ ninu ile Rẹ; K'a gbọ'rọ mimọ Rẹ. 6. Isinmi nla kan ku F'awọn eniyan Rẹ; Ọm'Ọlọrun, Alabukun Mu wa de 'sinmi Rẹ! AMIN
Hymn 029 – OLORUN wa orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia