Hymn 285 – Mura, elese, lati gbon | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Mura, elese, lati gbon" (C&S Hymn #285, Yoruba). Mura, ẹlẹsẹ, lati gbọn, Ma duro de ọjọ ọla; Niwọn b'o ti kẹgan ọgbọn,…

Hymn 285 – Mura, elese, lati gbon | C&S Yoruba Hymnary
Mura, ẹlẹsẹ, lati gbọn, Ma duro de ọjọ ọla; Niwọn b'o ti kẹgan ọgbọn, Bẹ l'o si sọrọ lati ri. Mura lati bere anu, Ma duro de ọjọ ọla; Ki igba rẹ ko ma ba tan, Ki ọjọ alẹ yi to tan. Mura, ẹlẹsẹ k'o pada, Ma duro de ọjọ ọla; Nitori k'ẹgun ma ba ọ, K'ọjọ ọla k'o to bere. f Mura lati gba ibukun, Ma duro de ọjọ ọla; Ki fitila rẹ ma ba ku, K'isẹ rere rẹ to bẹrẹ. Oluwa, y'ẹlẹsẹ pada, Ji kuro ninu were rẹ ; Ma jẹ k'o tapa s'imọ Rẹ, K'o ma f'ẹgbẹ rẹ se 'lọra. AMIN

Hymn 285 – Mura, elese, lati gbon | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia