Hymn 270 – JESU Oluf' okan mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Oluf' okan mi" (C&S Hymn #270, Yoruba). 1. JESU Oluf' ọkan mi, Jẹ ki n sala s'aya Rẹ, Sa t'irumi sunmọ mi, Sa ti…
1. JESU Oluf' ọkan mi, Jẹ ki n sala s'aya Rẹ, Sa t'irumi sunmọ mi, Sa ti iji n fẹ s'oke; Pa mi mọ, Olugbala, Tit' iji aye y'o pin, Tọ mi lọ s'ebute Rẹ, Nikẹhin gba ọkan mi. 2. Abo mi, emi ko ni, Iwọ lọkan mi rọ mọ; Ma f'emi nikan silẹ, Gba mi, si tu mi ninu; Iwọ ni mo gbẹkẹle, Iwọ n'iranlọwọ mi; Masai f'iyẹ apa Rẹ, D'abo b'ori aibo mi. 3. Krist 'Wọ nikan ni mo fẹ, N'nu Rẹ, mo r'ohun gbogbo; Gb' ẹni t'o subu dide, W'alaisan, at'afọju; Ododo l'oruko Rẹ, Alaisododo l'emi, Mo kun fun ẹsẹ pupọ, Iwọ kun fun ododo. 4. 'Wọ l'ọpọ ore-ọfẹ, Lati fi bor' ẹsẹ mi, Jẹ ki omi iwosan, Wẹ inu ọkan mi mọ; Iwọ l'orisun iye, Jẹ ki n bu n'nu Rẹ l'ọfẹ; Ru jade n'nu ọkan mi, Si iye ainipẹkun. AMIN
Hymn 270 – JESU Oluf' okan mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia