Hymn 252 – OLUWA, gbo aroye mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA, gbo aroye mi" (C&S Hymn #252, Yoruba). 1. OLUWA, gbọ aroye mi; Gbọ adura ikọkọ mi, Lọdọ Rẹ nikan, Ọba mi, L'emi…
1. OLUWA, gbọ aroye mi; Gbọ adura ikọkọ mi, Lọdọ Rẹ nikan, Ọba mi, L'emi o ma wa iranwọ 2. L'orọ Iwọ o gbohun mi, L' afẹmọjumọ ọjọ na, Ni ọdọ Rẹ l'emi o wọ; Si Ọ l'emi o gbadura. 3. Sugbọn nigb' ore-ọfẹ Rẹ, Ba mu mi de agbala Rẹ; Ọdọ Rẹ l'emi o tẹju mọ, Nibẹ, n o sin Ọ ni rẹlẹ. 4. Jẹ k'awọn t'o gbẹkẹlẹ Ọ, L'ohun rara wi ayọ wọn; Jẹ k'awọn t'Iwọ pamọ yọ, Awọn t'o fẹ orukọ Rẹ. 5. Si Olododo l'Oluwa, O na ọwọ ibukun Rẹ; Oju rere Re l'eniyan Rẹ, Yoo si fi se asa wọn. AMIN
Hymn 252 – OLUWA, gbo aroye mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia