Hymn 243 – OLUWA, ma moju kuro | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA, ma moju kuro" (C&S Hymn #243, Yoruba). 1. OLUWA, ma moju kuro, L'ọdọ emi t'o n yilẹ; Ti n sọkun ẹsẹ ayé mi,…

Hymn 243 – OLUWA, ma moju kuro | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA, ma moju kuro, L'ọdọ emi t'o n yilẹ; Ti n sọkun ẹsẹ ayé mi, N'itẹ anu ifẹ Rẹ. 2. Ma ba mi lọ sinu 'dajọ, Bi ẹsẹ mi ti pọ to; Nitori mo mọ daju pe, Emi ko wa lailẹbi. 3. Iwọ mọ, ki n to jẹwọ rẹ, Bi mo ti n se layé mi; At' iwa isinsin yii mi, Gbogbo rẹ l'O kiyesi. 4. Emi ko ni f‘ atunwi se, Ohun ti mo fẹ tọrọ; Ni iwọ mọ ki n to bere, Anu ni lọpọlọpọ. 5. Anu Oluwa ni mo fẹ, Eyi l‘opin gbogbo rẹ; Tori anu ni mo n tọrọ, Jẹ ki n ri anu gba. AMIN

Hymn 243 – OLUWA, ma moju kuro | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia