Hymn 236 – MOKANDILOGORUN dubule je | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MOKANDILOGORUN dubule je" (C&S Hymn #236, Yoruba). 1. MỌKANDILỌGỌRUN dubule jẹ, Labẹ oji nin' agbo; Sugbọn ọkan jẹ lọ…

Hymn 236 – MOKANDILOGORUN dubule je | C&S Yoruba Hymnary
1. MỌKANDILỌGỌRUN dubule jẹ, Labẹ oji nin' agbo; Sugbọn ọkan jẹ lọ or'oke, Jina s'ilekun wura; Jina rere l' or' oke sisa, Jina rere s'Olus' aguntan. 2. Mọkandilọgọrun Tirẹ leyi: Jesu, wọn ko ha to fun O?‖ Olus'-aguntan dahun, ―Temi yi, Ti sako lọdọ mi; B'ọna tilẹ ri palapala, N ó w'aginju lọ w'aguntan mi. 3. Ọkan nin' awọn t'a ra pada, Ko mọ jinjin omi na; Ati duru oru ti Jesu kọja, K'o to r'aguntan Rẹ he; L'aginju rere l'o gbọ 'gbe re, O ti rẹ tan, o si ti ku tan. 4. Nibo n'iro ẹjẹ ni ti wa, T'o f'ọna or' oke han? A ta silẹ f'ẹnikan t'o sako, K'Olusaguntan to mu pada Jesu, kil'o gun ọwọ Rẹ bẹẹ? Ẹgun pupọ l'o gun mi nibe. 5. Sugbọn ni gbogbo ori oke, Ati l'ori apata, Igbe ta l'oke ọrun wi pé, Yọ, mo r'aguntan mi he. Yọ, Jesu m'ohun Tirẹ pada. AMIN

Hymn 236 – MOKANDILOGORUN dubule je | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia