Hymn 229 – OLUWA alafia wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA alafia wa" (C&S Hymn #229, Yoruba). 1. OLUWA alafia wa, L'o pasẹ t'ọdun yipo; Awa ọmọ Rẹ wa dupẹ, F'ọdun titun…

Hymn 229 – OLUWA alafia wa | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA alafia wa, L'o pasẹ t'ọdun yipo; Awa ọmọ Rẹ wa dupẹ, F'ọdun titun t'a bere, Yin Oluwa! Yin Oluwa! Ọba nla t'O da wa si. 2. A dupẹ fun ipamọ wa, Ni ọdun ti o kọja; A mbẹbẹ iranlọwọ Rẹ, Fun gbogbo wa lọdun yi, Jẹ k'Ijọ wa, jẹ k'Ijọ wa Ma dagba ninu Kristi. 3. K'agba k'o mura lati sin, Lọkan kan ni ọdun yi; K'awọn ọmọde k'o mura Lati safẹri Jesu. K'alafia, k'alafia, K' o se ade ọdun yi. 4. K'Ẹmi Mimọ lat' oke wa, Ba le wa ni ọdun yi; Ki Alufa at'Olukọ, Pẹlu gbogbo Ijọ wa, Mura giri, Mura giri, Lati jọsin f'Oluwa. AMIN

Hymn 229 – OLUWA alafia wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia