Hymn 227 – OLORUN wa je k'iyin Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN wa je k'iyin Re" (C&S Hymn #227, Yoruba). 1. ỌLỌRUN wa jẹ k'iyin Rẹ, Gb'ohun gbogbo wa kan; Ọwọ Rẹ yi ọjọ wa…
1. ỌLỌRUN wa jẹ k'iyin Rẹ, Gb'ohun gbogbo wa kan; Ọwọ Rẹ yi ọjọ wa po, Ọdun miran si de. 2. Ẹbọ wa n goke sọdọ Rẹ, Baba, Olore wa; Fun anu ọdọdun ti n san, Lati ọdọ Rẹ wa. 3. N'nu gbogbo ayida ayé, K'anu Rẹ wa sibẹ; B'ore Rẹ si wa si ti po, Bẹni k'iyin wa pọ. 4 N'nu gbogbo ayida ayé, A n ri aniyan Rẹ: Jọwọ jẹ k'aanu Rẹ 'kanna Bukun ọdun titun. 5. B'ayọ ba si wa, k'ayọ naa Fa wa si ọdọ Rẹ; B'iya ni, awa o kọrin, B'ibukun Rẹ pẹlu. AMIN
Hymn 227 – OLORUN wa je k'iyin Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia