Hymn 225 – ODUN miran ti koja | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ODUN miran ti koja" (C&S Hymn #225, Yoruba). 1. ỌDUN miran ti kọja, Wawa l'akoko naa lọ, Ninu eyi t'a wa yi, Yoo…

Hymn 225 – ODUN miran ti koja | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌDUN miran ti kọja, Wawa l'akoko naa lọ, Ninu eyi t'a wa yi, Yoo s'arimọ ọpọ; Anu l'o fi da wa si, A ha lo anu naa bi? K'a bi 'ra wa ba se tan? B'a o pe wa l'ọdun yi. 2. Ayé bi ibi ija, Ẹgbẹgbẹrun l'o n subu; Ọfa Iku t'o si n fo A le ran s'emi b'iwọ, Nigb'a n wasu t'a si n gbọ, Oluwa, jẹ k'a saro; P'ayérayé sunmọle; A n duro l'eti bebe. 3. B'a gba wa lọwọ ẹsẹ, Nipa ore-ọfẹ Rẹ, Njẹ ―ma bọ‖ n'ipe o jẹ, K'a le lo, k'a r'oju Rẹ; F'eniyan Rẹ l'ayé yi, K'aanu wa l'ọdun titun; Ọdun t'o l'ayọ ju yi, L'eyi t'o mu wọn de 'le. AMIN

Hymn 225 – ODUN miran ti koja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia