Hymn 223 – OLORUN t'odun t'o koja | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN t'odun t'o koja" (C&S Hymn #223, Yoruba). 1. ỌLỌRUN t'ọdun t'o kọja; Iret' eyi ti mbọ; Ib'isadi wa ni iji, At'…

Hymn 223 – OLORUN t'odun t'o koja | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌLỌRUN t'ọdun t'o kọja; Iret' eyi ti mbọ; Ib'isadi wa ni iji, At' ile wa lailai. 2. Labẹ ojiji itẹ Rẹ, L'awọn eniyan Rẹ n gbe! f Titọ l'apa Rẹ nikansoso, Abo wa si daju. 3. K'awọn oke k'o to duro Tabi k'a to d'ayé, Lailai Iwọ ni Ọlọrun, Bakan naa, l'ailopin! 4. Ẹgbẹgbẹrun ọdun l'oju Rẹ, Bi alẹ kan l'ori; B'isọ kan l'afẹmọjumọ, Ki orun k'o to la. 5. Ọjọ wa bi odo sisan; Ọpọ l'o si n gbe lọ; Wọn n lọ, wọn di ẹni 'gbagbe; Bi ala ti a n rọ 6. Ọlọrun t'ọdun t'o kọja, Iret' eyi ti mbọ; Mas' abo wa 'gba 'yọnu de; At' ile wa lailai. AMIN

Hymn 223 – OLORUN t'odun t'o koja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia