Hymn 212 – OJO ati akoko n lo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO ati akoko n lo" (C&S Hymn #212, Yoruba). 1. ỌJỌ ati akoko ń lọ, Wọn ń sun wa s'eti, 'boji Awa fẹrẹ dubulẹ na, Ninu…

Hymn 212 – OJO ati akoko n lo | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌJỌ ati akoko ń lọ, Wọn ń sun wa s'eti, 'boji Awa fẹrẹ dubulẹ na, Ninu iho 'busun wa. 2. Jesu, 'Wọ Olurapada, Ji ọkan t'o ku s'ẹsẹ; Ji gbogbo ọkan ti ń togbe. Lati yan ipa iye. 3. Bi akoko ti ń sunmọle, Jẹ k'a ro 'bi ti a ń lọ; Bi lati r'ayọ ailopin, Tabi egbe ailopin. 4. Ayé wa ń lọ! Iku de tan, Jesu, sọ wa, Tit' O fi de, K'a ba Ọ gbe, K'a ba Ọ ku, K'a ba Ọ jọba titi lailai 5. Ayé wa ń kọja b'ojiji, O si ń fo lọ bi 'kuku; Fun gbogbo ọdun t'o kọja, Dariji wa, mu wa gbọn. 6. Kọ wa lati ka ọjọ wa, La ti ba ẹsẹ wa ja, K'a ma sare, k'a ma togbe, Tit'a o fi ri 'sinmi. 7. Gbogbo wa fẹrẹ duro na, Niwaju itẹ 'dajọ; Jesu, 'Wọ t'o sẹgun iku, Fiwa s'apa ọtun Rẹ. 8. Ayé wa ń lọ! Iku de tan, Olugbala! Jọ pa wa mọ, K'a ba Ọ ku, K'a ba Ọ jọba titi lailai. AMIN

Hymn 212 – OJO ati akoko n lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia