Hymn 146 – ELEDA gbogbo ayé | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ELEDA gbogbo ayé" (C&S Hymn #146, Yoruba). 1. ẸLẸDA gbogbo ayé Ni asẹ Rẹ ni, Awa pejọ loni, Lati yin O‘okọ Rẹ. A dupẹ…
1. ẸLẸDA gbogbo ayé Ni asẹ Rẹ ni, Awa pejọ loni, Lati yin O‘okọ Rẹ. A dupẹ lọwọ Rẹ, Baba Olore, Ki 'bukun Rẹ ọrun, Ba le gbogbo wa. 2. Tọju wa Baba ọrun, Larin ayé wa yi, Pa wa mọ k'o bọ wa, Pese f'aini wa. 3. Kérúbù, Séráfù, Ẹ m'ọkan yin le, Awa ni Baba nla, T'o mọ ẹdun wa. 4. Kérúbù, Séráfù, Ẹ d'amure yin, Ẹ ma fi aye silẹ, Fun ẹmi esu. 5. Ẹyin asaju wa, Ẹ ku'sẹ Ẹmi, Ọlọrun alaye, Yoo wa pẹlu yin. 6. Ẹyin Aladura, K'ẹ ma gbadura, Mẹtalọkan y'o gbọ, Y'o sẹgun fun wa. 7. Gbogbo ẹyin agan, Baba yoo pese, Ẹyin ti ẹ bimọ, Gbogbo wọn yoo la. 8. Ẹyin t'ẹ si loyun, Jah yoo s'abo yin, Ẹyin t'ẹ ko ri se, Jah yio pese. 9. Ogo ni fun Baba, Ogo f'Ọmọ Rẹ, Ogo f'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lai. AMIN
Hymn 146 – ELEDA gbogbo ayé | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia