Hymn 001 – JI okan mi, ba orun ji | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JI okan mi, ba orun ji" (C&S Hymn #001, Yoruba). 1. JI, ọkan mi, ba orun ji Mura si isẹ oojọ rẹ; Mase ilọra, ji kutu,…
1. JI, ọkan mi, ba orun ji Mura si isẹ oojọ rẹ; Mase ilọra, ji kutu, K'o san gbese ẹbọ oorọ. 2. Ro gbogb' ọjọ t'o fi sofo; Bẹrẹ si rere 'se loni; Kiyes' irin rẹ laye yi; K'o si mura d'ọjọ nla ni. 3. Gba ninu imọlẹ ọrun, Si tan 'mọlẹ na f'ẹlomi, Jẹ ki ogo Ọlọrun rẹ, Han n'nu wa ati ise rẹ. 4. Ji, gbọn 'ra nu 'wọ ọkan mi Yan ipo rẹ larin Angẹl, Awọn ti wọn n kọrin iyin, Ni gbogbo oru s'Ọba wa. AMIN
Hymn 001 – JI okan mi, ba orun ji | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia